CBN Ní Òun Kò Ní Erongbà Àtẹ̀jáde Irúfẹ́ Owó Míràn Báyìí

  1. §Ile ifowopamo apapo Ile yii, Central Bank of Nigeria (CBN) ti soo di mimo bayi pe oun ko gbero lati se afikun fun awon irufe Ipele owo ti a n na lorileede yii lodun 2024 gege bi iroyin kan se n gbee kiri. Ninu atejade kan ti eni ti o je adari leka ikansiraeni fun Ile ifowopamo ohun, Isa Abdulmumin fi lede lori opo ayélujára ‘X’ re taa mo si twitter teleri nibe lo ti salaye yii wipe iroyin naa kii se otito rara ati wipe eyi ti won ṣe lojo naa ti won tun sese gbe jade naa je okan lara awon iroyin ti o ti jade lati odun 2007.

O ni Ile ifowopamo apapo Ile yii ko ni erongba agbejade ipele owo tuntun lodun yii tabi lodun to n bo, Nitorinaa o ni ki enikeni mase naani iroyin eleje ọ̀hún ati wipe owo ti a n na, lorileede Naijiria bayi naa ni naira marun (#5), naira mewa (#20), aadota náírà (#50), ogorun naira (#100), igba naira (#200), eedegbeta naira (#500) ati Egderun kan náírà (#1000) to je oba owo bayi.

Leave a Reply

Back To Top