Awon molebi Baba agba, eni aadorin odun 70 years, Aminu Ajayi ti o je òṣìṣẹ́ ijoba teleri ti awon jandulu kan seku pa nipinle Ogun ni won ti n beere bayi fun idajo ododo lori iku ti o pa baba ati egbon won.
Iroyin soo di mimo wipe awon janduku kan lo sekolu si baba agba yii lojo kerin, osu keje odun taa wa yii ninu ile re to wa lagbebge Imasayi, Ariwa Yewa, nipinle Ogun ti won si fi ada saa titi ti emi fi bo lenu re. Enikan lara awon aburo oloogbe naa, Adebisi Ajayi so fun awon oniroyin lọ́jọ́ Aje tó kọjá yìí wipe o je ohun iyalenu fun oun latara bi ile ise olopa to n ri si iwa esun odaran eyi to wa ni Eleweran nipinle Ogun ko se ri ohunkohun ni pato se si oro naa lati bii osu merin seyin ti isele naa ti se, ti won si n wo awon afurasi lori oran naa nira, ó ní èyí náà ló fà á tí àwọn se gbé igbese láti fi to ile ise olopa to wa ni alagbon leti nitoripe iku ti o pa egbon oun ko gbodo lo lasan bee ati wipe asiko ti won seku paa naa lo ye ko maa joro awon ohun to ti jise jiya fun.
Nigbati won kan di agbenuso fun tie ise olopa to wa ni Alagbon, ASP Oluwakemi Mayegun, O je ko di mimo pe komisona olapa yoo ni lati sapade ati iforowanilenu wo pelu awon molebi ologbe ati awon afurasi nínú osu kokanla odun yii.