Àwọn Jàndùkú L’ọlọ́pa ń lò fi Ṣiṣẹ́ Nipinlẹ̀ Èkó

Awon awako lagbegbe Berger ati Oshodi nipinle Eko ni won ti n ke gbajare bayi, ti won si n soo di mimo wipe awon janduku ni awon agbofinro nlo lawon agbegbe yii lati maa gba owo lowo awon lojoojumo.
Gege bi Tolulope se fi to awon oniroyin leti, o ni owo ti awon n san fun awon omo ganfe yii ti won mo si ‘aja olopa’ lojumo ko din ni eedegberin #700 naira ati wipe oloko to ba kuna lati san owo naa, yoo fimu danrin.

Opolopo awon awako miran ati awon alabasisepo won lọ kin oro naa leyin ti won si soo di mimo wipe gbogbo iwonyi naa wa lara awon ohun to n je ki owo oko maa won gogo laarin igboro.
Gbogbo igbinyanju lati kan si agbenuso ile ise olopa eka ti ipinle Eko, SP Benjamin Hundeyin lori oro naa lo ja si pabo.

Leave a Reply

Back To Top