Egbe awon osise ni orile-ede yii,iyen Nigeria Labour Congress NLC, ati akegbe re ,Trade Union Congress TUC ni won jo bu enu àte lu Iwa ti Gomina ipinle Imo, Hope Uzodinma hu latari ikolu ti awon kan se si Aare egbe awon osise, Ògbení Joe Ajaero ni ipinlé Imo ni ojoru ose yii, ni asiko igbati won se ifehonuhan nibe
Egbe NLC ati TUC ti wa se ileri wipe, awon yio gbé igbese lati tako gomina Hope Uzodinma lori iwa abuku naa, latari akiyesi ti won se wipe o ni Owo ninu ikolu oun.
Uzodinma so ninu oro re wipe, Joe Ajaero ko tele Ilana iselu ati egbe awon osise,leyi ti o mu ki o wa dasi oro egbe awon osise ni ipinle oun ni asiko ti ko toó leyin ti gbogbo awon osise pata, ti gba Owo osu ati ajemonu won, sugbon ti Ajaero pelu awon arije ni ibi ibaje kan gbinmo po lati ba oju ijoba ohún je, ti o mu ki won fi maa polongo wipe ohún ko ti san Owo osu fun awon osise eyiti o fa sababi ifehonuhan won.
O ni, bi o ti le je wipe Omo bibi ipinle Imo ni Ajaero, ko gbodo da Ilana egbe po mo ti Oselu sugbon awon egbe osise ati oloko-owo ti se ileri wipe Oro ohún ko ni lo lasan pelu Hope Uzodinma.