Adajo Agba Kan Ni Ilu Abuja Ti So Fun Ajo EFCC Ki O Jowo Godwin Emefiele (Iroyin Itanilolobo) Friday,03 November,2023

Lana ojobo ti o je ojo keji osu kokanla odun ti a wa yii, ni Adajo O.Adeniyi ti Ile ejo giga ti o fidi kale si ilu Abuja , pa ni ase wipe, ki ajo ti o gbogun ti Iwa ajebanu ati sise owo ilu kumo-kumo , Economic and Financial Crime Commission EFCC ki o yanda Godwin Emefiele ti o je gomina teleri ni ile ifowopamo apapo ile wa kuro ninu akoko won, Adajo Adeniyi ni o pa lase leyin ti awon agbejoro fun Emefiele ti se atotonu pelu Iwe ipejo ti o ni ibuwolu Adajo agba ni ile yii ninu.

Iroyin fiyewa wipe, ajo EFCC lo fi owo sinku ofin mu Emefiele,ni kete ti ajo DSS yanda re kuro ni akolo won, ni eyi ti o ti wa lati ojo kewa osu kefa odun ti a wa yii

Ile ejo ti wa sun igbejo re bayi si ojo kokanla osu kokanla odun ti a wa yii.

Leave a Reply

Back To Top