Ajo National Economic Council Ti So Wipe Ijoba Apapo Ti N Gbé Igbese Lati Se Atileyin Eto Ogbin Fun Gbogbo Ipinle Lorile-ede Naijiria (Iroyin Itanilolobo) Friday,24 November,2023

Ajo ti o n se amojuto idagbasoke ilu, iyen National Economic Council lo so di mimo ni ana wipe, ijoba apapo n se Igbese lati se atileyin eto ogbin fun gbogbo ipinle merin-din-logoji ni orile-ede Naijiria,ijoba n gbero lati se idasile isé ti yio to milionu mejidinlogun ,titi kan awon agbe ti yoto egbeerun-lona-ogorun kakiri ilu.

Won ni ,ipele akoko yio wo ipinle Kano, Kaduna, Kwara,Ogun,Oyo, Imo,Cross-River, titi kan olu ilu ile wa Abuja ,ti yio si naa Owo ti yio to eedegbata ati Ogun Milionu dollar titi odun 2028.

Iroyin n je ko ye wa wipe, awon ipinle merin-din-logbon ti o ku naa n gbero lati darapo mo ipele elekeji,ni ibi ti awon alenuloro o ti se atileyin eto naa pelu Owo bilionu kan dollar ,won ni awon ipinle yii yio beer eto won laipe yii, titi odun 2024.

Minisita ti o risi eto ogbon ti o tun n se amoju ounje, Abubakar Kyari, lo so oro yii do mimo ni ile igbimo asofin ipinle leyin asekagba eto imu ilu gboro ,elekankandinlogoje iru re,eyiti won se Po pelu igbakeji Aare Orile-ede Naijiria Kashim Shettima ninu ogba ile Aare ti o wa ni ilu Abuja ni ana ojobo.

Leave a Reply

Back To Top