Ajo kan ton mojuto eto isuna ati ise isiro Iyen Socio-Economic right and accountability project SERAP lano ojo aiku ni won ti ro are banki agbaye ogbeni Ajay Banga lati dawo yiya awon ipinle merindinlogoji orilede Naijiria yi lowo duro latari bi won ti nse owo ilu kumokumo papajulo awon owo ti won ti ya ni ile ifowopamo agbaye oun ti won ko le isiro le lori
Bakanna ni ajo oun ro banki agbaye wipe ki o wodi awon gomina ipinle merindinlogoji orilede lati salaye bi won ti naa billionu mejo abo owo dollar ti won ya.
Ajo SERAP oun ninu gbolohun ti o tenu enitoje igbakeji adari re Kolawole Oluwadare so, salaye wipe koni pe ti awon gomina oun yoo fi ba ibasepo orilede yi je pelu banki agbaye oun latari iwa ajebamu owo ilu naa nitori ajo ton mojuto gbese ilu Iyen Nigeria debt management ti je ko di mimo wipe gbogbo gbese awon ipinle orilede yi ti di trillionu mesan o le perese lowo naira ti tijoba apapo si ti le die ni trillionu mejidinlaadorin owo naira.
O wa pari oro re wipe awon yoo maa reti ki awon gomina naa o wi tenu won lokookan lori esun oun bi koba ribe.