Ile Ejo Gigajulo Ile Naijiria Ti Fi Opin Si Awuyewuye Ti O Jeyo Leyin Idibo Aare Lorile-ede Yii (Iroyin Akoyawo) Friday,27th October 2023

Lana ojobo ti o je ojo kerindinlogbon osu kewa odun ti a wa yii ni ile ejo gigajulo ni ile yii fi opin si ija awuyewuye ati idukoko moni lori oro ijawe olubori ti awon elegbe Oselu lorisirisi ni ibi ti a ti ri egbe Oselu People’s Democratic party leyi ti Alhaji Atiku Abubakar ti o dije du ipo Aare ni abe re ati Peter Obi lati inu egbe Oselu Labour ti lewaju awon alatako oun pelu awon egbe Oselu miran.

  1. Ile ejo gigajulo oun,ninu igbimo awon Adajo eleni meje ni ibi ti a ti ri Adajo Inyan Okoro ti o le iwaju’ won , ni won ti pa ni ase wipe ki awon egbe Oselu alatako pelu awon alatileyin won lo so ewe agbeje mowo lori oro awuyewuye oun ati wipe Aare Bola Tinubu ni yio sii maa tesiwaju gegebi Aare orile-ede Naijiria gegebi abajade ti ajo olominira eto idibo ile yii INEC se kede ni ojo kini osu keta odun yii lori idibo si ipo Aare ti o waye ni ojo kedogbon osu keji odun ti a wa yii bakana.

Aare Tinubu ni ile ejo ti da lare bayi lati tesiwaju ninu isejoba odun merin gbako fun ti saa yii.

Leave a Reply

Back To Top