Wọ́n ti ni kí àwọn Dókítà máa lò tó ọdún márùn-ún kí wọ́n tó lè rìnrìn àjò lọ sí òkè òkun

Eni to je giwa ati oga agba yan-an-yan fun Ile eko giga fasiti ti oro ìlera, University  of Medical Sciences (UNIMED)eka ti Ipinle Ondo, Ojogbon Adesegun Fatusi lo ti gba ijoba orileede Naijiria nimoran bayii lori oro awon akeko jade lori oro eto ilera lawon Ile eko giga fasiti ti ijoba apapo lorileede yii, o ni ki won je kii awon akeko wonyii maa t’owo bo’ we adehun lati sin orileede yii to je Ile baba won ni o kere tan odun marun-un ki won to le gba won laaye lati ririn ajo lo soke okun.

Fatusi lo n gba ijoba ni amoran nibi ipade apero olodoodun ti ajo to n ri si oro eko nipa eto ilera nile yii, iyen Association Of Clinical And Academic Physiotherapist Of Nigeria ( ACAPN ) eyi ti wọ́n ṣe kẹ́yin O gbamoran yii lojuna lati pakodina bi opolopo awon akosemose Dokita onisegun oyinbo se n kuro nile yii lo si oke okun eyi ti o n se akoba fun idagbasoke oro eto ilera nile wa. O menuba bi awon osise nile eko giga fasiti , ti won ti janfani ijoba se maa n towobo iwe adehun , ki won tó le rin irin ajo lo soke okun, bi beko won yoo ni lati san iye owo kan pada fun ijoba , bee lo wa ro ijoba lati ri daju’ pe won se ipese awon ohun amayederun fun awon dokita onisegun oyinbo ati awon ohun ti yoo jeki Ise won rorun leyi ti won yoo maa fi fokan bale sise nile baba won.

Leave a Reply

Back To Top