ijoba ipinle Eko labe isakoso Gomina Babajide Sanwo-Olu ti so di mimo pe oun yoo mu oro eto ilera lokun kúndùn bayi fun awon olugbe nipinle Eko.
Gomma Sanwolu so oro yi nigba to ngbalejo minista to ń risi eto ilera ati itoju nipinle naa, Dokita Tunji Alausa l’Ojoru tó kọjá yìí ni agbegbe Marina nipinle naa.
Gómìnà gboriyin fun Aare Bola Ahmed Tinubu bo se yan awon minister to ti koju osuwon pelu re lati mu ki eka eto ilera to yanranti wa fun gbogbo omo orikede.
Gomina Babajide Sanwolu wa fi nda dokita Alausa loju wipe ijoba ipinle Eko ti setan lati tele ilana ati igbese ti o ba ti palase ti yoo si mu irorun ba eto ilera lai gun enikeni nipa nipinle naa.
Benani Dokita Alausa fi idunu re han si ijoba apapo pelu ifowosowopo ijoba ipinle Eko lojuna ati mu edinwo ba eto ilera fun igbaye gbadun awon olugbe nipinle naa