Lọ́jọ́rùú tó jẹ́ ọjọ́ kefa osu kokanla Odun 2024 ni ile eko Community Nursery and Primary School Ilapo se ayeye ifigagbaga ere idaraya onílé-ilé (Inter-house sport competition) leyi ti awon akeko nile eko naa ti fakoyo ninu ere idaraya lorisirisi pelu atileyin awon oluko won to fi mọ́ ifowosowopo awon obi,alagbato ati awon onile to n sagbateru fun Ile kookan.
Ninu oro ti eniti o je alaga nile eko náà, Ajihinrere Peter Idowu Enitinwa ba awon asojukoroyin latilese Radio Irawo 92.1fm so, nibe lo ti so nipa pataki ere idaraya pelu bi o se je ohun kan ni gboogi ti n mu ara ji pepe.
Bakan naa ni Oluso Agutan Y.A Adegbemi je ko di mimo wipe o je ona ti ife ati isokan fi n raaye fidi mule lawujo.
Oga ile eko yìí, Abileko Ajayi Janet je ko di mimo wipe ona ti awon obi n gba mú inú awon omo dun ni nigbati Abileko Bíọdún Olusola ti o je alakoso ere idaraya ni Zone 1 je ko di mimo wipe latara ifigagbaga ere idaraya yii ni won ti maa n ri awon omode ti won ni awon ebun adamo amutonrunwa leka ere idaraya ti ijoba si maa n dide iranlowo fun won lati so won di eniyan nla nidi rẹ.
Ó wa gba awon obi ati alagbato niyanju lati maa gba awon omo won laaye ki won o maa se ere idaraya fun oniruru anfani lokan ojokan to wa ninu re
Lara awon eeyan jankan-jankan to peju pese sibe ni: Olori Niniola ti o je Ayaba Isegun Ife Odaye, Asoju CAC Itedo Yiyanju ti o ni ile Green, Prophet Akinruli ti o ni ile Blue, Chief Canice Onwadiwe ti o ni ile Pink, Baale Ilapo Community ti o ni ile Purple, S.P .Philip ti o ni ile Yellow, Abileko B.Olabisi ti o soju Onimo-Ero Bode Olabisi ti o ni ile White ati awon eeyan jankan-janka miran.