Ilé Ẹ̀kọ́ De Genius Olivet College Ti jawe olubori láàrin àwọn ilé Ẹ̀kọ́ Girama Iyookun ní Ìpínlẹ̀ Ògùn Nínú Ìdíje Asekagba Imọ Sayẹnsi

Asekagba idije Ìmò nípa Sayensi èyí tí àwọn olùkọ́ nínú ìmọ̀ sayensi ọ̀hún tí a mọ sí All Nigerians Science Tutors Eka ti Ìpínlẹ̀ Ògùn ,èyí tí wọ́n ṣe ní àná ọjọ Kejìlá oṣù kẹfà ọdún 2025 nílùú Abẹ́òkúta .

Nibẹ ni ile iwe De Genius Olivet College tó wà ní Tigbo ní ìjọba Ìbílẹ̀ Ado Odò Ọta ní ìpínlè Ogun tí jawe olubori láàárín àwọn ilé Ẹ̀kọ́ tí wọn tó Ọgọ́san 180 tí wọn kópa nínú ìdíje ọ̀hún .

Níbi ìdíje náà ni a ti rí ilé Ẹ̀kọ́ Gíga yìí ,tí wọ́n ṣe àgbékalè Ẹ̀rọ àgbelẹ̀rọ kan èyí tí wọ́n fi ń gbin oko àti ẹ̀rọ èyí tó ń fọn Apakokoro oko ìyẹn Herbicide spraying machine .

Leyii tí ó mú àwọn ilé ìwé yìí tayọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga iyookun tí wọn jẹ́ Akẹgbẹ́ wọn ,èyí tí wọ́n jọ kópa níbi ìdíje ọ̀hún .

Ẹ o rántí wí pé ní ọdún 2024 tí ó kọjá yìí ni ilé Èkó De Genius Olivet College kópa nínú irúfé ifigagbaga yìí ,tí wọ́n sì gbẹyẹ lọ́wọ́ àwọn Akẹgbẹ́ wọn tó kun latara bí wọn ṣe ṣe ipò Kínní

Latara eléyìí náà ni Honourable Hammed Omisore fi imoriri hàn fún àwọn Olùkọ́ tí wọ́n ṣe akoyawo àti kíkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún ,tofimo àwọn ọmọ náà ,fún bí wọn ṣe fakoyo nínú ìdíje náà to wáyé lánàá òde yìí

Leave a Reply

Back To Top