Okàn lara awon senato teleri ni orile-ede Naijiria ti o soju arin gbun-gbun ipinle Zamfara ,Kabiru Marafa ni o ti fi lede ni opin ose ti o koja yii wipe, Aare Bola Tinubu ti setan lati fi owosowopo pelu awon alatako re ti won dije du ipo Aare ,ti won si fi idi remi lati Inu egbe oselu people’s democratic party ati egbe Oselu Labour iyen Alhaji Atiku Abubakar ati Peter Obi ni ilepa isokan ninu isejoba re.
Marafa ni o fi oro oun lede leyin ipade kan ti o se pelu Aare Bola Tinubu ni opin ose ti o koja yii, o ni sugbon ifowosowopo oun yio dale iha ti awon adije fidiremi oun koo si idajo ile ejo gigajulo ni orile-ede yii lori awuyewuye ti o teyin idibo naa jade, bi won ba gba ejo naa, ti won si setan lati lepa alafia ati itesiwaju orile-ede yii bi won ti se so siwaju ni akoko ipologo idibo , o ni Aare paapa ti nawo re sile lati gba won wole si Inu isejoba re.
O tesiwaju wipe, looto oun kin se Aare sugbon ninu ipade ti oun se pelu Aare Tinubu,ni Aare ti beere lowo oun wipe boya ki oun tesiwaju ninu ipinu oun niti lilepa isokan pelu awon adije fidiremi oun abi ki oun da won nu lati maa ba isé oun lo, sugbon esi ti oun fun Aare ni wipe, iha ti won ba ko si idajo ile ejo gigajulo naa ni yio so irufe Igbese ti Aare yio gbé lori Oro naa.