Omodekunrin Eni Odun Merinla Gba Emi Ara Re Ni Ipinlé Cross -River (Iroyin Itanilolobo) Monday,30th October 2023

Ninu ilailo ati iyalenu ni awon olugbe Ekondo ni ilu Calabar ipinle Cross -River was, latari bi Omodekunrin kan eni odun merinla se fi okun bata gba emi ara re.

Omodekunrin oun ti oruko re nje Donald ni won ni ongbe pelu iya-iya re ni apa guusu ilu oun.

Iroyin Fi lede wipe,okan lara ore omode oun, Eyi ni o se alaye wipe, leyin ti Donald pari isé ile re ni owuro ojo abameta ti o koja yii, ni o jade lati lo ra fufu, ti o si je arimo ti awon ri, titi di ago mejila ti iya-iya re ké gbajari sita lati wa awon ti yio wa ba gbé Omo naa ni ibi ti o ti fi okun bata so ara re mi orule.

Nigbati awon ajo olopa de ibi isele oun, won Koo lati fi owo kan oku Omo naa, ti won si ni ki iya-iya re ki o gbe sugbon ti oun paapa Koo nitori ohún iyalenu ni o je fun gbogbo awon ti won gan-ni isele oun bi Omo naa yio ti fi okun bata so ara re laisi ohún ti o fi ti ese gun orule naa.

Okan lara awon ti o gan-ni isele naa ni, lati ojo satide oun ni Omo naa ti n fi ara han oun, ti o si sunkun fun idajo, eyi ni o mu ki oun ni igbagbo wipe iku Omo naa ni Owo kan abosi iya-iya re ninu.

Irene Igbo ti o je agbenuso fun ajo olopa ni ipinlé Cross-River ni, oun ko ti ni oye isele oun ni kikun sugbon bi oun ba de enu isé ni owuro ojo aje oni, oun yio maa se iwadi fini-fini Lori Oro oun.

Leave a Reply

Back To Top