Ààrẹ Bọ́lá Tinúbú Àti àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lọ́jọ́ ìṣẹ́gun Tuesday ti gbé ìgbé sẹ̀ láti Dáwọ́ Ìyọnípò gómìnà Ìpínlẹ̀ Rivers siminalayi Fubara Dúró,
Ààrẹ ṣe ìpàdé pẹ̀lú Gómìnà náà àti Ọ̀gá rẹ̀, tó kúrò lórí àlééfà tó tún jẹ́ mínísítà olú ìlú wa Àbújá, Nyesom Wike, nílé ìjọba ní Àbújá,
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Bouchi, Bala Muhammad, sọ eléyìí di mímọ̀n kété lẹ́yìn tí àjọ Agbófinró ṣe ìpàdé pọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ lábẹ́ ìjọba Tinúbú.
Wike àti Fubara ló wà nínú ìpàdé tí wọ́n nílé ìjọba ọ̀ún, tí àwọn oni ìròyìn rí wọn tí wọ́n ń bọ ara wọn lọ́wọ́
Bákan náà ni wọ́n rí àwòrán àti fán rán tó fi hàn bí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ṣe ń kìló fún àwọn oni ìròyìn nínú ilé ìjọba pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe àfihàn ìpàdé náà kí Wọ́n má bàa lé wọn kúrò nínú ilé ìjọba.
Ele yìí ṣẹlẹ̀ bí àwọn agbófinró ṣe fi ọwọ́ sìnkún òfin mún àwọn ọ̀dọ́ tó tó ọgọ́fà níbi tí Wọ́n tí ń fi ẹ̀hónún hàn lórí Ìyọnípò gómìnà.
Alamí ṣe àwọn oniroyin pé àwọn ọ̀dọ́ gbìyànjú láti ya bo ibùgbé agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀n aṣòfin Ìpínlẹ̀ Rivers, matins Amaewhule, ni ìlú porhacourt, tí àwọn ọlọ́pàá sì dá wọn lọ́wọ́ kọ́ nípa yí yìn ìban sókè.
Àwọn ọ̀dọ́ náà ni kí Amaewhule kúrò nínú ilé ìgbìmọ̀n aṣòfin pé kì í ṣe agbẹnusọ mọ́n.
Àwọn ọ̀dọ́ yìí gbìyànjú láti bi géètì ilé agbẹnusọ lulẹ̀ tí Wọ́n sì ń pariwo pé kó fi ilé ìgbìmọ̀n aṣòfin sílè ṣùgbọ́n tí àwọn ọlọ́pàá dá wọn lóhùn l’ẹ́yẹ ọ̀ṣọkà tí Wọ́n sì fi ọwọ́ òfin mún wọn.
Ìròyìn sọọ́ di mímọ̀n pé àṣìta ìban ba ọ̀dọ́ kan tí wọ́n sì gbe dìgbà dìgbà lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú