Aare Bola Tinubu ni Iroyin ti Fi lede bayi wipe o ti te pepe Owo ti o to trillionu metadinlogbon ati aabo Owo naira(27.5trillion) gegebi Owo isuna fun odun 2024 siwaju awon omo ile igbimo asofin lana ode yii ti o je ojo kokandinlogbon osu kokanla odun 2023.
Gegebi eni ti o je onimoran si Aare lori oro Iroyin ati ikansiaraeni, Ajuri Ngelale se fi to awon oniroyin leti Lana ojoru , o ni Aare se eleyi ki o to di wipe o te oko leti lo si ilu Dubai nile United Arab Emirate(UAE) ni ibi ti o to lo se ipade po pelu awon akegbe re yooku ni agbeye Lori oro ayipada oju ojo.
Ajuri Ngelale se alaye siwaju si wipe Aare ti so di mimo ninu oro re ni asiko ti o n se alakale bi won yio se naa Owo oun fun eto isuna odun 2024 ,wipe awon ti yio je pataki afojusun lori eto isuna oun ni oro eto aabo ,eyi ti o ti mehe lati ehin wa wipe, o gbodo duro ire ati wipe ipese isé fun awon ti ko ni ise lowo.
Bakana ni idagbasoke gbodo de ba awon igun kookan ni orile-ede yii, o ni Aare se afikun wipe oun yio lo eto isuna oun fun ifilole ipinle rere ti yio mu idagbasoke ba eto oro aje ile wa.