Aare Bola Tinubu Ni Iroyin Ti So Wipe Yio Wa Ni Ibi Ipade Adura Kan(Iroyin Itanilolobo) Thursday,30 November 2023

Aare Bola Ahmed Tinubu ni Iroyin so di mimo wipe yio wa ni ibi ipade adura pataki,eyi ti won yio te pepe re ni ola ti o je ojo eti ojo kinni osu kejila odunti a awa yii mini gbongan ile ijosin gbogboogbo fun awon elesin kristeini.

Eyi ti a mo si National Ecumenical Center ti o wa ni ilu Abuja.

Ni ibi ipade adura oun, ni Sultan ti Ile sokoto, Alhaji Saa’d Abubakar III ati awon otokun ilu Mii ni orile-ede yii yio peju pese si ibe gegebi eniti o je alaga Egbe awon omo leyin Kristi iyen Christian Association Of Nigeria(CAN) eka ti ipinle Eko, Bishop Stephen Adegbite se so fun awon oniroyin lana ojoru .

O ni won gbé ipade adura oun kale lati se atileyin fun isejoba Aare Tinubu lori awon oniruru idojuko ti isejoba naa n koju lati igba ti o ti bere ati lati ri daju wipe,igbora eni ye pelu isokan Fi ese mule ni orile-ede yii.

Bakana ni ki erongba iso ireti dotun ti mo si Renewed Hope Agenda eyi ti Aare Tinubu piyamo ninu isejoba re yii se aseyori ni awon Eka kookan.

O se alaye siwaju si wipe,Aya Aare Senator Oluremi Tinubu ni yio je iya ojo naa nigbati George Akume ti o je akowe si ijoba apapo yio je alaga ni ibi ipade adura oun, eniti o je olusoaguntan ati Alabojuto agba fun ijo Deeper Life Bible Church, olusoaguntan W.F Kumuyi yio je oludanileko pataki nibe.

Ni ibi ipade adura yii kana ni eniti o je Aare ile igbimo asofin Godswill Akpabio,awon gomina ni Ile yii bi, Babajide Sanwo-olu ti o je gomina ipinle Eko,Omo oba Dapo Abiodun gomina ipinle Ogun,pelu awon lenu-lekan ati otokun ilu ninu isejoba ati awon asoju esin yoo ti peju pese sibe.

Leave a Reply

Back To Top