Aare Bola Tinubu Ti Dasi Awo Ti O Wa Laarin Gomina Ipinle Ondo Ati Igbakeji Re (Iroyin Itanilolobo) Monday,27 November 2023

Aare Bola Ahmed Tinubu ni o ti daasi awon ti nlo ni ipinle Ondo laarin gomina Rotimi Akeredolu ati igbakeji re Ògbení Lucky Ayedatiwa.

Eniti o je onimoran pataki fun Aare Tinubu lori oro ifilede , Ajuri Ngelalelo fi oro oun lede lana ojo aiku, o salaye wipe ,gomina Akeredolu ati igbakeji re Ayedatiwa ti pinu lati Pana awo ti o wa laarin won, ki won si fi owo sowopo pada bi ti ateyinwa.

Oro oun lo waye ninu ipade ti won se Pelu Aare ni ilu Abuja eyi ti o gba won to wakati mefa gbako

O salaye siwaju si wipe, won se adehun olojo gbogboro pelu Aare, igbakeji Aare,awon asoju fun gomina Akeredolu,awon asofin ipinle ati apapo awon adari egbe Oselu APC ati bebelo

O ni Aare wa gba gbogbo awon ti o ni ikusinu tabi awo si ara won lati ti Owo re bole,ki won o si gba alaafia ati ifarajin laaye laarin won, o wa roo gbogbo awon Omo egbe asofin ni ipinle naa lati tesiwaju ninu ise won.

Igbakeji gomina naa wa ni,oun Setan Lati fi ohún gbogbo ti o ti sele seyin, ti o si seleri lati mu ki alaafia o joba ati lati le je ki ohun gbogbo maa lo ni irowo-irose ni ipinlé naa.

Leave a Reply

Back To Top