Ajo awon osise Ile eko giga ti a mo si Academic staff union of universities (ASUU) eka ti ipinle Bauchi ti n fon rere re bayi wipe, awon Omo Ile eko giga ko nilo eyawo ni akoko ti won wa ni ile eko,bikose ki ijoba o se eto Owo iranwo fun won.
Eniti o je adari ajo ASUU yii eka ti ipinle Bauchi, omowe Lazarus Maigoro lo so eyi ni ana ode yii ni asiko ti won n fun awon Omo Ile eko ti o to bi mokandinlogun ni eko ofe ni Ile eko giga Abubakar Tafawa Balewa, ti o wa ni ipinle Bauchi.
Maigoro ni, ohun inira ni io je fun awon akeko yii lati le san owo ti won ba yaa yii pada nigbati won ba setan ni Ile eko giga naa ati wipe eleyi le da iko okan soke ni akoko ti won ba shi wa ni ile eko.
O tesiwaju wipe Ajo ASUU eka ti ipinle Bauchi ti n sise lori akojopo awon Omo Ile eko ti o sesee ki won fi Ile eko sile ni opin saa ti won nlo lowo-lowo yii, won wa roo ijoba lati tun ero won pa lori eyawo ele ti won pinu lati fun awon omo Ile eko giga, ki won si ropo re pelu Owo iranwo lati le mu awon ti ko ni anfani lati San owo Ile eko won je anfani yii.