Àjọ Lagos Mega Youth Festival Ṣe Àjọyọ̀ Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

Ọjọ́ Ẹtì tí ó jẹ́ ọgbọ́n ọjọ́ oṣù kẹjọ tí a wà yìí ni àjọ kan tí ó ń ṣe Kóríyá fún àwọn Ọ̀dọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó ,Lagos Mega Youth tẹ pẹpẹ ayẹyẹ ìmọrírì Ààrẹ Orílẹ̀ èdè yìí ,Asiwaju Bola Ahmed Tinubu .

Ayẹyẹ yìí tí ó wáyé ní agbègbè Abúlé Ẹ̀gbá ní Ìpínlẹ̀ Èkó ni ó jẹ́ elẹ́ẹ̀kẹsán-án irú rẹ ,níbi tí àwọn Ọ̀dọ́ àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni Ìpínlẹ̀ Èkó ti ń ṣe àfihàn àwọn ẹ̀bùn àdámọ́ wọn ,tí wọ́n sì ń ṣe ìwúrí fún wọn ní ọlọ́kan-ò-jọ̀kan nípa fífi àmì Ẹ̀yẹ dá wọn lọ́lá látara bí wọn ṣe tayọ nínú ìfigagbága àti ìdíje nínú Ẹ̀kọ́ Ìmò Ìṣirò ,àròkọ ní èdè gẹ̀ẹ́sì àti Ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ǹsì .

Bákan náà ni wọ́n tún ṣe Kóríyá fún àwọn tí wọn ní ẹ̀bùn orin kíkọ ,kàkàkí fífọn,ìlú lílù ,ijó jíjó ,ewì kíké àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ .

Ẹni tí ó jẹ́ olùdásílẹ̀ àti aṣáájú Àjọ Lagos Mega Youth Festival yìí,Ọ̀gbẹ́ni Bọlá Olabisi nínú ọ̀rọ̀ rẹ sọ fún àwọn asojúkọ̀ròyìn láti ilé isẹ Rédíò Ìràwọ̀ 92.1 fm nípa bí ètò ọ̀hún ti ṣe ń so èso rere láti ọdún kẹsàn-án tí wọn ti bẹ̀rẹ̀ rẹ jákèjádò Ìpínlẹ̀ Èkó àti ipa rere tí ó ń kó nínú ayé àwọn Ọ̀dọ́ fún ọjọ́ iwájú wọn .

Bákan náà ló fi ìmọrírì hàn sí àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ nínú ìṣèjọba ní Ìpínlẹ̀ Èkó ní Ẹ̀ka ti ìjọba ìbílẹ̀ àti ti Ìpínlẹ̀ ni àwọn tí wọn tún peregedé nípa fífi àmì Ẹ̀yẹ dá wọn lọ́lá .

Lára àwọn tí wọ́n gba àmì ẹyẹ náà ni Honourable Toyin Aremu tí ó jẹ́ Onímọ̀ràn Pàtàkì sí Kọmísọ́nà fún Ìrìnà ọkọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkó ,Honourable Dr Tokunbo Oluwole ti Lagos Mainland ,Honourable Ahmed Alabi Buyaminu ti Àpápá ,Honourable Dare Ojole A.k.A (Eagle)Orílé Agege àti àwọn lórúkọ lórúkọ mìíràn .

Leave a Reply

Back To Top