Ajo olopa ni ipinlé Ogun ni o ti rowoto awon omo wewe meji kan ti ojo ori won koju mefa ati mesan lo lori esun wipe won danasun ile eko won eyi ti o wa ni agbegbe Isheri -Olofin ni abe ijoba ibile Ifo ni ipinle Ogun.
Oga olopa Omolola Odutola ti o je alukoro fun ajo olopa ni ipinlé Ogun ni o fi oro naa lede ni ilu Abeokuta ti o je olu ilu ipinle naa ni ojo aje oni, o se alaye wipe oun ko le se alaye bi awon Omo naa ti se ni anfani si yara ikeko won ni ile eko community primary school ti o wa ni iseri olofin, ti won si fi Ina si awon Iwe ti o wa ni Yara ikeko oun, ki o to di wipe Ina naa gbinaya mo won lowo.
O ni oloye kan ni adugbo naa ti o gan-ni isele naa ni o fi oro oun sun ajo olopa tii eka isé ti o n se iwadi Iwa odaran ninu ile isé Olopa ti o wa ni tosi agbegbe naa si se abewo si ibi isele naa.
Odutola se alaye siwaju si wipe, awon ti n sa ipa won lati ri awon obi awon omode naa nitori oran ti won ti oru bo oun ,o ni bi o tile je wipe, o seese ki o je wipe enikan ni o fi irufe ise bee ran awon omo oun, sugbon awon yio maa fi ohún ti o ba je abajade iwadi ajo olopa lede fun mutu-muwa.