Eniti o je akowe fun ijoba apapo Orile-ede Naijiria, George Akume ni ti fi lede bayi wipe, oun ni idaniloju wipe ojo ola orilede yii yio dara ati wipe ki awon Omo Orile-ede yii maa so ireti nu ninu isejoba orile ede Naijiria
Akume lo soro idaniloju yii ni ibi ipade adura at iyin kan ti won pe ni National Solemn Assembly eleyi ti won se agbekale re lati fi dupe lowo Olorun fun orile ede Naijiria, ni olu ilu Ile wa Abuja ni opin ose ti o koja yii.
O salaye wipe, orile-ede Naijiria je akanda kan , sugbon ohun ti o nilo ni awon adari rere ti won ni afojusun, eto rere ati ipinu rere fun orile-ede Naijiria.
O wa ro awon Omo Orile-ede yii lati maa gbadura fun awon adari re ati lati ma gbadura fun ilosiwaju orilede Naijiria bakana.
O tesiwaju lati tun ro awon Omo Orile-ede yii lati fowosowopo pelu isejoba Aara Bola Tinubu ki o le se akoyawo gbogbo erongba rere ati awon afojusun rere ti o ni fun gbogbo Omo Orile-ede Naijiria.
Eniti o je alaga egbe awon omoleyin Kristeni iyen Christian Association of Nigeria (CAN) Bishop Stephen Adegbite, ti o kopa nibi Ipade naa, roo awon Omo orilede Naijiria lati maa se atileyin fun isejoba orile-ede Naijiria, ki alafia ki o le joba ni Ile wa Naijiria.