- Awon afurasi agbebon kan ni Iroyin fi lede wipe won se ikolu si awon agbegbe kan ni Ipara Remo ati Ode Remo ti awon omo ile eko giga gbogbonise ti gateway Sapade mulesi labe ijoba ibile Ariwa Remo ni Ipinle Ogun ti won si yibon ba awon akeeko lokurin kan tun ba awon akeeko lobinrin fipa Lopo.
Iroyin so di mimo wipe ojo eti meji to koja yi ati ojo aiku ano ni deede agogo kan ooru ni awon agbebon oun sekolu si awon akeeko naa, ko won leru tun se won nisekuse, lara awon ti won fara kasa Ota ibon ni omodekunrin kan ti won poruko re ni Francis Dwumfor .
Okan lara awon olugbe agbegbe oun toko lati foruko ara re lede nitori eru salaye wipe oun kagbako irufe ikolu be ni odun to koja ti oun si na owo toto millionu meta ki oun to yiro. Bakanna, ni Olatunji Alexandre to je Are awon akeeko naa ni o je oun ibanuje fun awon nitori awon ke ipe pajawiri si awon olopa ni akoko isele naa ti awon ko si gbo oun koun latodo won.
Won wa ro ijoba ipinle oun lati tepele mo ise aabo ni agbegbe oun ki awon to gbe igbese ti koni bojumu.Omolola Odutola, ti o je alukoro ajo olopa ni ipinle nigbati on jeri si isele oun ni looto ni isele oun buru jai sugbon kosi enikeni ti o baalo o wa salaye wipe ajo olopa ti ipinle ogun ti pe ipade po pelu awon igbimo isakoso ti awon akeeko ile eko oun pelu awon asoju agbegbe naa lati wa iyanju si oro abo ti o mehe nibe.