Awon Olugbe Ni Agbegbe Abakaliki Ni Ipinle Ebonyi Ti Ké Gbajere Sita

Awon olugbe ni agbegbe Abakaliki ni ipinle Ebonyi, ti n ké gbajare bayi latari bi awon alokolounkigbe n se Fi ojojumo yo won lenu ni agbegbe oun.

 

Iroyin fi ye wa wipe, ojojumo ni awon jaguda Pali oun ati awon omo elegbe okunkun n fi damu awon olugbe ti o wa ni ijoba ibile Abakaliki leyi ti ko Fun won ni ifokan bale lati gbé ninu ile tabi lo si ibi okoowo won

 

Gegebi enikan ti o je olugbe ni agbegbe oun,abileko Chineye Orji se Fi to awon oniroyin leti ni ana ojoru, o ni osan gangan ni awon alokolounkigbe maa n yaa wo adugbo ,ti won si maa nko ounje ati awon ohún elo miran, o so siwaju si wipe won tun maa n gbé ero POS lo ka awon eniyan mo ile lati gba owo ti o wa ninu apo ikowosi won pelu ibon.

 

O salaye siwaju si wipe awon Iwa ikoni nipapa mora yii ti mu ki awon maa le sun fori so sunka leyi ti won n fin rawo ebe si ijoba lati dude si oro eto abo to Peye ni agbegbe oun.

 

Gbogbo igbiyanju awon oniroyin lati kan si ile Isé olopa ti o wa ni Abakaliki ni o jasi pabo.

Leave a Reply

Back To Top