Àwọn Ọ̀yọ́mèsì Fẹ̀hónú Hàn Lórí Àpèrè Aláàfin

Opolopo awon omo bibi ilu Ọ̀yọ́ lọ́jọ́ Iṣẹ́gun tó kọjá ni won ti n fehonu han ni woorowo leyi to mu ki won lo duro si enu ona abawole Ile ejo giga ti Ọ̀yọ́ to wa nilu Awe latari bi ijoba ipinle Ọ̀yo ati awon Ọ̀yomesi ṣe n fi oro yiyan Alaafin tuntun fale.
Ninu Ifehonu han yii ni won ti gbe patako orisirisi dani pelu akole bii: ‘Eyin Oyemesi, e ma tele owo, isese ni kee tele’ ‘Apere Alaafin kii Se fun tita’ ‘E je ki otito o Leke’ ati bee bee lo.
Oro yii naa lo si wa nile ejo giga tilu Oyo leyi ti Ile ejo loni ojo Iegun ti sun ayewo re si Ọ̀jobo ti o je ojo keji osu kokanla taa wa yii nibi ti awon afobaje maraarun yoo ti wa nibe pelu gomina ipinle Ọ̀yo, Seyi Makinde, komisona fun oro ijoba ibile ati oye jije, komisona sun eto Idajo ati adajo agba fun ipinle Ọ̀yo ti gbogbo won yoo ni lati wa nikale lati forí ikoko soodun lori rè.

Leave a Reply

Back To Top