Ayẹyẹ Ìgbàyọ̀ǹda Ṣeun Ọmọ́le Ní Ilé Iṣẹ́ Rédíò Ìràwọ̀ 92.1 fm.

Ọjọ́ Àbámẹ́ta Satide, Ọjọ́ keedogbon osu karun odun 2024 ni Oluwaseun Omole ti o je okan lara awon ti o n kẹ́kọ̀ọ́ nipa imo ise ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ gba ìyọ̀nda nile iṣẹ́ Radio Irawo 92.1Fm leyin ti awon alase ti buwolu pe o ti peregede, o fi gbọ̀ọ̀rọ̀ jẹkà nibi ise naa.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ awon èèyàn tó peju pésẹ̀ sibi ayẹyẹ ọ̀hún ló jẹ́rìí gbèé gẹ́gẹ́ bii oniwa tutu ti o si farabale lati kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú onírúurú àwọn amúyẹ ti wọ́n fi ṣàpèjúwe rẹ̀.

Lára àwọn èèyàn tó wà níbi ayẹyẹ náà ni Aláṣẹ ati olùdarí ileese Radio Irawo 92.1 Fm, Onimọ̀-ẹ̀rọ , Bode Olabisi, Bode Edogbemi, ti o je Oga Agba ile ise ọ̀hún , Abileko Bukola Olabisi, Adedayo Ladipo, Folake Azeez Oniwarere, Ismail Ojelade ati awon èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn míì

Leave a Reply

Back To Top