Ayẹyẹ Ìsìn Ìdúpẹ́ ọdún kẹẹ̀dógún fún ìrántí ìyá wa Olóògbé Snr Mother In Israel Adedoyin Iyabode Sobo (Nee Adams )tó wáyé ní ọjọ́ Àìkú tó jẹ́ ọjọ́ kejilelogun oṣù kẹsàn-án ọdún 2024 tí a wà yìí nínú gbọ̀ngàn ilé ìjọsìn Sacred Cherubim And Seraphim El-Bethel Shiloh Cathedral tó wà ní 68,Ipaja Road ,Oke Kòtò Agege Ìpínlẹ̀ Èkó .
Níbi ìsìn ìrántí ọ̀hún ni wọn ti ṣe àpèjúwe Olóògbé náà gẹ́gẹ́ bíi ìyá rere tí ó kóni mọ́ra ,tí ó sì tún nífẹ̀ẹ́ gbogbo ènìyàn dénú dénú pẹ̀lú onírúurú akitiyan rẹ̀ nínú ìjọ àti lókè eèpẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi Olùṣọ́ Àgùntàn Oníwàásù Elder Apostle Olufemi Gbogboade JP ṣe sọ lásìkò ìwàásù lábẹ́ ìdarí Olùṣọ́ Àgùntàn Àgbà Snr Elder Apostle (Dr)Adebola Olubunmi Odubela (JP).
Àwọn Ọmọ,ẹbí ,ará ,ọ̀rẹ́ tó fi mọ́ àwọn ọmọ-ọmọ pẹ̀lú ọkọ Olóògbé náà Pa Olusoji Ọ̀tọ̀lórìn Ṣóbọ̀ JP ni wọn bá àwọn asojúkọ̀ròyìn láti ilé iṣẹ́ Rédíò Ìràwọ̀ 92.1 fm sọ̀rọ̀ tí wọn sì ṣàpèjúwe ìyá náà gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rere tí irú rẹ ṣọ̀wọ́n láwùjọ àti bí wọn kò ṣe lè gbàgbé rẹ̀ láàárín ẹbí .Wọ́n sì gbà á ní àdúrà pé kí Ọlọ́run túnbọ̀ tẹ́ẹ sí afẹ́fẹ́ rere .
Lára àwọn Lóókọ-lóókọ tó tún wà níbi ayẹyẹ náà ni Abilékọ Bukola Olabisi ,Ọ̀gbẹ́ni Olanrewaju Ṣóbọ̀ ,Abilékọ Kíkẹ́lọmọ Ṣóbọ̀,Abilékọ Olaitan Ṣóbọ̀ ,Abilékọ Adetoro Ajétúnmọbí,Elder Apostle Paul Olabisi,Snr Apostle Bola Olabisi ,Elder Apostle Yomi Onítìmírìn ,Sup. Apostle Peter Oguntide ,Sup. Apostle Mother Oluremi Àjíkẹ́ Akíngbadé àti àwọn ènìyàn jànkàn jànkàn mìíràn .