De-Genius Olivet College Tún Ti Peregedé Nínú Ìdíje JETS Àti STAN Nílùú Abuja

Ile eko De Genius Olivet College to wá n’ilu Ota, Ìpínlẹ̀ Ogun niroyin ti fi lede bayi wipe o lewaju laarin awon ile eko to to gbangba sun loye lorileede Naijiria lawon to kopa ninu idije ifigagbaga lori imo,ti egbe awon ojewewe nile eko girama ti won n kọ́ nipa imo ero ati ijinle sayensi.

Iyen Junior Engineers Technicians and Scientists (JETS) Ninu eleyi ti won ti gbegba oroke gege bi ile eko to se ipo kini laarin awon akegbe won to ku nipinle Ogun.

Bakan naa ni won fakoyo ti won si tun wa loke tente ninu eyiti awon egbe olukoni ninu imo ijinle sayensi (Science Teachers Association of Nigeria) STAN Sagbekale re ti o je ti gbogbogbo lorileede Naijiria lapapo.

Nibi idije ti JETS eyi ti DE-Genius Olivet College ti lo soju ipinle Ogun nilu Abuja lana Ọjobo, nibe ni won ti gba ipo keji ni gbogbo orileede Naijiria, lyen laarin awon ipinle merindinlogoji (36) to wa nile yii.

Latara eleyi naa ni àjọ to n ri si oro eto ẹ̀kọ́ leka ti ipinle se fi aami eye da won lola gege bi ile eko to peregede julo laarin awon akegbe won nibiti Muritala Moshkuur Adedipupo ati Lawal Nimot Orahachi ti sójú awon oje wewe ile eko girama nipinle Ogun leka ti JETS ti awon ipele giga nile eko ohun sise ipo kini leka idije ti STAN. Oludasile ile eko naa, Hon. Ahmed Omisore wa fi imoriri han lopolopo fun aseyori yii ti o si tun dupe lowo awon oluko ti won sugba awon omo naa pelu idaniloju pe ile eko De Genius Olivet College ko ni rowọ́ lati maa te siwaju lori oro imugbooro eto eko lati sanfani fawujo.

Leave a Reply

Back To Top