Egbe oselu ti o n se ijoba lowo-lowo ni orile-ede Naijiria iyen All Progressive Congress ni o ti ko iwe si egbe ti o n baniwi ninu ajo amofin orile-ede yii lori Iwa ifenu tenbele ejo ile ejo giga julo ni orile-ede yii ti alaga apapo egbe Oselu Labour Julius Abure ati agbenuso fun ipolongo ninu egbe Oselu naa Kenneth Okonkwo se.
Ninu iwe ipejo oun ti akowe agba egbe Oselu APC senato Ajibola Basiru bu Owo lu , ni o ti se alaye wipe Iwa ti Julius ati Okonkwo wu je Iwa arinfin ti oun si ni ero wipe o ye ki awon paapa mo wipe o je itabuku si ajo amofin orile-ede yii latari eyi ki won o lo wii ti enu won.
Nigbati eniti o je akowe ifilede fun egbe oselu labour, Obiorah Ifoh n fi esi si oro oun ni ale ana ojo aiku ana, o ni Iwe ipejo naa je eri si gbogbo awuyewuye ti o ti n rugbo bo tele wipe Aare Tinubu yio fi oju Peter Obi ati egbe Oselu Labour danrin leyin idajo ile ejo ti o ga julo oun.