Gomina ipinle Ogun, omoba Dapo Abiodun ni o ti roo awon adari esin jake jado lati tepele mo ojuse won lati mu iyanju ba awon ohun ti orile-ede yii dojuko ni akoko yii.
Gomina lo so eyi ni ibi ifilole awon oloye titun kan ti o waye ni ijo The Apostolic church, Nigeria ni ipile Eko.
O salaye wipe, awon alakale eto nlo lowo lori bi ayipada ati itesiwaju yio se de ba eto oro aje orile-ede yii ti o si so wipe ojuse ijo ko se fowo ro seyin ninu awon alakale yii.
Komisona fun eto isuna ati agbekale ogbeni Olaolu Olabimtan ti o soju gomina naa se alaye wipe, yiyan awon ojise olorun meji otooto si ipo se afihan igbagbo ati ifarajin won si awon alakale ijo.
Gomina Dapo Abiodun wa ro gbogbo eniyan lati tun ero won pa ati lati ni ifarajin ti o loorin papa julo awon Omo ijo Aposteli ni orile ede Naijiria eka ti pinle eko lati se atileyin fun awon adari titun ti ijo naa.