Ìgbimo àwọn alenuloro ninu isejoba apapo lorileede yii lọ́jọ́ Aje ose yìí ti buwolu ìgbésẹ̀ eyawo ti ko ni ele Lori ti o fere to bilionu meta aabo dollar $3.4 lati banki apapo agbaye (World Bank) eyi ti won fe na Lori awon eto onikoko marun otooto. Gege bi minista fun eto isuna ati isakoso oro aje lorileede yii, Wale Edun se salaye fun awon oruroyin, o ni awon akanse eto ti won fe lo owo naa si ni oro Ina oba, atunse awon ohun amusagbara oro ipinle, eto Eko ati ironilagbara fun awon obirin to ti dagba. Wale Edun so siwaju sii wipe owo ti won ya yii ni sisan re yoo bere leyin ọdún mewa si akoko yìí, iyen lodun 2033 ti wọn yoo si fi odidi ogoji odun san- an.