Igbimo isakoso awujo kan ni ipinlé Oyo ni won to rawo ebe si eka ile isé ijoba apapo ti o mojuto oro ise ati awon agbasese ti won mojuto isé oju ona marose Ibadan si Oyo, Ogbomosho ati Ilorin lati falemo isé opopona oun latari ijamba ti o n waye nibe ni ojo kerinla osu yii ti o si so eniyan meedogun di ero orun alakiji.
Isele aburu oun ni won ni o pa oko Mazda eleni merindinlogun kan ti o gbera lati ibudoko Owode po mo oko akoyoyo nla ti o saidede yi owo mo awako Mazda oun ni ibi ti o ti gbero a ti yoo kuro ni egbe re.
Alaga igbimo isakoso awujo Oyo oun ti won n pe ni (Oyo metropolitan Development Association) Arch Bishop Emeritus Ayo Ladigbolu nigbati o lewaju awon jakan-jakan miran lo se pade po pelu awon asoju ile isé ijoba ipinle oun, ni oun ti tele Oba ana ti o waja iyen Alaafin Lamidi Adeyemi keta wa fun irufe ebe yii ri.
O ni oun ti so di mimo ri wipe ,ijoba ti o ba mojuto oju ona ni o se gudu-gudu meje fun awon ara ilu.