Ijoba ibile idagbasoke Agbado okeodo ni ipinle Eko Ti pinu lati maa pa won wole larata ero ibanisoro lodo awon oloko-owo fun odun 2024.
Erongba yii di mimo lati enu alagba ijoba ibile idagbasoke oun,Hon. David Oladapo Famuyiwa, ninu iforowanilenuwo ti o waye ni ibi apero eto isuna odun 2024 ni ojobo ose ti o koja yii.
Hon. Famuyiwa so wipe, igbese lati pa owo wole si agbegbe yii maa je ki awon ri Owo ti o po daada gba wole, ti o si mu adikun ba bi Owo won n se sonu.
O ni, awon ti pe awon akose-mose lati wa se idanileko fun awon osise won lori bi won yio ti se aseyori lori Igbese naa.
O safikun wipe,ohún ti awon ara ilu nilo ni ,ki won so apo ikowosi ijoba ibile naa moo ero ibanisoro won, bee lo ki awon olukopa ni ibi apero oun kaabo, ti o si roo gbogbo awon olori leleka- njeka, ki won fi ipinle ti yoo mu idagbasoke baa oro aje awon eniyan lagbegbe naa leyi ti yoo je ko rorun fun won lati San Owo Ori ijoba.
O ni awon n foju wo agbekale ti yoo mu ko rorun fun won lati ni ibasepo pelu awon ile isé aladani latari a ti se aseyori ninu eto isuna odun 2024.
Hon. Famuyiwa tun Fi da awon eniyan loju wipe ,eto isuna odun 2024 yio fi aaye itesiwaju sile fun Mii, lati le mu ki awon akanse isé ti won dawole ko yori ati lati je ki idagbasoke oro aje awon olugbe ijoba ibile Agbado okeodo.