Ijoba Ipinle Eko Ti Daa Awon Ile Itaja Woo Ni Agbegbe Ikotun (Iroyin Awujowa) Monday,30th October 2023)

Awon olokowo ati oloja ti ijoba daa ile itaja won woo latari imugboro agbegbe ikotun ni abe ijoba ibile Alimosho ni ipinlé Eko ni won ti ké gbajari sita fun iranwo.

Iroyin je ko di mimo wipe, awon ile itaja ti o to aadorun ni ijoba daawo ni odun 2020, ti awon osise ijoba ipinle Eko si se ileri fun won wipe awon yio fun won ni Owo gba maabinu leyin ti won ba sise oun tan.

Awon kan ti Inu nbi lara awon onsowo ati oloja oun ni won ti WA fi aidunu won han fun awon akoroyin ni ojo abameta ti o koja yii wipe ijoba ko lati mu ileri re se.

Oloja kan, Innocent Umeze ti o ni ile itaja meji lara awon ti won daawo oun ni okankan ile itaja oun to milionu meta naira, o wa se alaye siwaju sii wipe eka isé ti o n mojuto irinkerindo ati isé igberiko se ileri fun awon leyin eyi ni won tun awon ile itaja ti won bake ni akoko isele endsars se,ti won ko si se awon eto ti won se ileri re fun awon.

Onisowo miran, Kolawole Ademola ni, awon ile itaja oun fi nwa jije mimu fun oun ati idile oun sugbon lati akoko ti won ti dawo ni atije atimu ko ti rorun mo fun oun ati ebi oun ti ijoba si ko lati mu ileri re se.

O ni oun ti o bani ninuje julo ni wipe, ijoba koi se ohunkohun leyin ti won da awon ile itaja oun wo.

Eniti o je alaga agbegbe Ikotun/Igando ,Lasisi Akinsanya nigbati on soro lori oro oun, ni ise oun ko si ni Owo ijoba ibile sugbon ijoba ipinle, ti won si ti yan igbimo kan ti Lara awon ontaja oun papa wa pelu.

Komisona fun oro ifilede, Gbenga Omotosho ni oun yio se iwadi Lori Oro oun,oun yio si bu awon oniroyin gbo.

Leave a Reply

Back To Top