Ilé Ẹ̀kọ́ De Genius Olivet College Tayọ Nínú Ìdíje Ẹgbẹ́ JETS

Ile eko De Genius Olivet College to wa nilu Ota nipinle Ogun ni won ti jawe olubori bayii ninu ifigagbaga awon akeko to wa ninu egbe Junior Engineers Technicians and Scientists Contest (JETS) iyen eko Imoju-ero ati Ijinle Sayensi laarin awon akeko nile eko giga jakejado ipinle Ogun.


Ifagagbaga yii lo wáyé l’Ojobo ti o je ojo keje, osu kokanla, odun 2024 nilu Abeokuta ti o je olu ilu ipinle Ogun. Nibiti awon akeko ti won danto latile eko De Genius Olivet College; Muritala Moshkuur Adedipupo ati Lawal Nimat Orahachi ti tayo, ti won si gbeye lowo awon akegbe won toku.


Awon omo wonyi ni won wa nipo kini, ti won si gba iwe eri: “Mo peregede” latowo eni ti o je Komisona fun oro eto eko nipinle Ogun, Ojogbon Arigbabu gege bi eni to fakoyo julo.


Awon naa ni won yoo lo soju ipinle Ogun ninu idije asekagba iru re ti yoo je ti gbogbogbo lawon ipinle jakejado orileede Naijiria, eyi ti yoo waye nilu Abuja

Leave a Reply

Back To Top