Ile Isé Omo Ogun Oju Omi Lorile-ede Naijiria Ti Reburu Oko Oju-Omi Nla Kan(Iroyin Itanilolobo) Friday, 03 November 2023

­Ile isé Omo ogun oju omi Lorile-ede Naijiria, Nigeria Navy ni won ti so di mimo wipe, won reburu oko oju omi nla kan, eyiti won fin gbé epo ni ona aito lati orile-ede yii, ni ibudo epo tii Atlas Cove,eyiti o je eka kan lara ile isé ti o risi oro epo bentiro ni orile-ede Naijiria NNPCL.

Oga Agba ti o je ogagun fun iko awon Ogun oju omi BEECROFT, commodo Kolawole Oguntuga so di mimo fun awon oniroyin lana ojobo lati enu agbenuso re,sub Lieutenant Happiness Collins wipe won reburu awon jaguda yii ni ojoru ti o koja yii,ti won sise iwadi wipe, won lo awon roba ifapo lati maa fa ninu awon opa epo ti o je ti orile-ede yii.

O tesiwaju ninu oro re wipe,awon eniyan yii raye sise nlabi naa lati ara awon opa epo ti o ti baje ati eyiti o ti foo, ti won si n tibe faa epo jade, o wa to Ile isé NNPCL lati gbé igbese fun amojuto ati atunse ti o ye lori awon opa epo ti o ti foo kakiri ni orile-ede yii, bakana ni o so di mimo wipe Iko awon ko ni dekun lati maa gbogun ti awon onifayawo epo ti won ngbe gba ori omi ni orile ede yii, ni eyiti o n se akoba fun oro aje ile wa.

­

Leave a Reply

Back To Top