Komisona olopa ni ipinlé Enugu, Ògbení Kanayo Uzuegbu ni o ti n pase wipe ki iwadi o bere ni pereu lori awon Iwa kudie kudie kan ti o n waye laarin awon agbofinro ni agbegbe Nsukka ni ipinlé naa.
O ni, oun ti pase fun igbakeji komisona ipinle yii lati tete bere iwadi lati le fi oju awon asebi yii hande latari awon ifehonuhan ti awon eniyan fi n han lori ero ayelujara.
O wa roo awon olugbe ipinle naa lati mu suuru nitori wipe oun yio sa gbogbo ipa oun lati fi opin si awon Iwa ibaje ti o ti woo awon agbofinro kan lewu ni ipinle naa.