Eniti o je Minisita fun oro eko ni orile-ede yii, Tahir Mamman ni o ti fi erongba ijoba apapo han lori a ti gbogun ti awon idojuko ti o n yo awon ogowere lenu eko eleyi ti o n ranle gbengben ni orile-ede yii lowo-lowo.
O fi oro oun lede fun awon oniroyin ni ojo aiku ana ni ile isé ijoba ti o wa ni Uyo ti o je ilu ilu ipinle Akwa-ibom.
O gboriyin rabande fun ijoba ipinle Akwa-ibom fun isé takuntakun ti won se sinu awon ile eko ti o se abewo si.
O ni, ayika awon ile eko oun dun wo de bi wipe o le mu ki eni ti ko ni Ife a ti ka Iwe tun ero re pa leyi ti yio ran eto Eko orile-ede yii paapa lowo ni ibamu pelu erongba Aare Tinubu lati so awon ile eko kakakiri do ohún iwuri, sugbon ise oun nilo ifowosowopo ijoba ibile,ipinle ati ijoba apapo.
Gomina ipinle naa paapa ni, bi ijoba apapo be le mu isé naa lokukudun, yio dun mo oun ninu nitori yio mu erongba oun naa wa si imuse kankan, yio si ran isé oun lowo lati tun awon ile eko se ati lati da awon oluko ni eko sii.