Aare Bola Ahmed Tinubu niroyin soo di mimo bayi pe o ti da si rogbodiyon to n lo lowo bayi nipinle Rivers laarin Gomina Siminelayi fubara ati Nyesom Wike to sese kuro lori aga gomina nibe, to ti wa di minista fun olu ilu Ile wa Abuja bayi.
Iroyin fi to wa leti pe ibasepo to wa laarin Nyesom Wike ati Fubara ni ko dan moran bii ti ateyinwa latari bi awon igun kan ninu Ile igbimo asofin ipinle naa se gbe igbese lati yo fubara nipo leyin ti awon eni aimori kan fina sun apakan Ile igbimo asofin ohun lojo Aiku to koja.
Bio tile je pe awuyewuye kan n lo labenu wipe gbogbo igbiyanju lati yo Gomina Fubara nipo naa lo lowo Nyesom Wike ninu eyi naa lo faa ti Aare Tinubu fi da si oro ohun ki alafia le joba ni iha mejeeji ati ni ipinle naa lapapo.