Gomina ipinle Abia, Alex Otti ti soo di mimo bayii pe Oja maluu ti won n pe ni Lokpanta Cattle Market, eyi to wa ni agbegbe Umunneochi, lopopona marose, Enugu si Portharcourt yoo di oja ti awon eniyan jakejado orileede yii yoo maa fi ojoojumo na bayii ati wipe ko ni je oja maluu nìkan mó bikosepe won yoo maa ta awon orisirisi nnkan miran nibe.
- Otti lo n soro yii lojo Isegun to koja yìí lasiko to n ba awon oniroyin soro lori akoyawo ise iriju re eyi to maa n se losoosu, O ni oun pase naa lati le gbogun ti iwa ipanisayo ti o n waye ninu awon igbo to wa lagbegbe oja ọ̀hún latari bi awon eso alaabo se ri awon oku eniyan ti o ti n jera bii aadota (50) ati awon ogun (20) miran ti ko lori lorun won bee ni akaimoye awon egungun gbigbe ti won sawari ninu igbo to wa lagbegbe oja naa.
O salaye siwaju sii pe iroyin to oun leti pe inu igbo yii ni awon ajinigbe maa n lo fi boju fi sise laabi won ti won si ti n gbowo lowo awon molebi eni to ba lugbadi won.
O ni bi oja yii yoo ti se je ojoojumo bayi ni awon eso agbofinro ati alaabo wa lorisirisi lati maa sabojuto iwole ati ijade awon eniyan ti ko si ni si aaye fun igbo kankan lagbegbe oja naa leyi ti ko ni faaye gba awon amookunseka eda.