Lẹ́yìn onírúurú ìkìlọ̀ tí wọ́n ti ṣe fún àwọn ọlọ́jà tí wọ́n máa ń pàtẹ ọjà wọn sí ojú ọ̀nà tí àwọn ẹlẹ̀sẹ̀ ń rìn lágbègbè ìjọba ìbílẹ̀ ìdàgbàsókè Agbado Òkè odò LCDA.
Èyí náà ló mú kí alága ìjọba ìbílẹ̀ ìdàgbàsókè yìí, Hon. David Oladapo Famuyiwa wá ṣe kìlọ̀-kìlọ̀ fún àwọn ọlọ́jà láti dẹ́kún à ń pàtẹ sí àwọn ojú ọ̀nà wọ̀nyí àti ẹ̀gbẹ́ títì lèyí tí ó lè mú kí wọ́n rí ojú pipọ́n ijọba.
Famuyiwa sọọ́ di mímọ̀ wípé àkàìmọye ìgbà ni wọ́n ti kìlọ̀ fún àwọn ọlọ́jà wonyi àmọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọtí ìkún gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún ìjọba ìbílẹ̀ ìdàgbàsókè náà, Olóyè Akinwumi Odeyemi ṣe sọọ́ di mímọ̀ lónìí Ọjọ́bọ tí ó jé ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù karùn-ún ọdún 2024 lásìkò tí wọ́n ń ṣèpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ìgbìmọ̀ ìdàgbàsókè àdúgbò lágbègbè ọ̀hún, ìyẹn CDC èyí tó wáyé níléẹṣẹ́ ijoba ti Agbado Òkè odo LCDA.
Ó sọ síwájú sii wípé àwọn ọlọ́jà lágbègbè Kọ́lá, Abule-Egba, Command àti Òkè odò làwọn ojú ọ̀nà wọ̀nyí ni wọn yóò máa fọwọ́ ṣìkún òfin mú bí wọ́n bá tún gbé irúfé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ láti máa pàtẹ sì ẹ̀bá ọ̀nà èyí tí ó lè máa di lílọ bíbọ̀ ọkọ̀ tàbí àwọn èèyàn lọ́wọ́.
Ẹni tí ó jẹ́ alága Ìgbìmọ̀ CDC, Ogbeni Ernest Kasumu sọọ́ di mímọ̀ níbi ìpàdé náà wípé wọ́n gbé ìgbésẹ̀ náà láti ṣe àfọ̀mọ́ àwọn àgbègbè wọ̀nyí àti ojú ọ̀nà wọn gbogbo.
Ó sọ síwájú sii wípé àìtẹ̀lé òfin ìṣàfọ̀mọ́ náà yóò máa mú ìfàsẹ́hìn bá àwùjọ wa. Ó ní nítorí ìdí èyí ijọba kò ní fojú ire wo àwọn tí wón bá mu pé wọn ń hùwà àìtọ́ náà.