Wọ́n Ti Ṣíṣọ Lójú Ọkọ̀ Tí Yóò Máa Lọ Afẹ́fẹ́ CNG Nipinlẹ̀ Ogun

Gomina Ipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun ni iroyin fi lede pe o ti siso loju awon oko boosi ti yoo maa lo afefe Compressed Natural Gas ( CNG ) dipo epo bentiroluu lati le maa fi se igbokegbodo awon eniyan ipinle ohun lona ti yoo fi ro won lorun gege bi okan lara awon alakale ijoba fun awon ohun atura lori oro owo iranwo ori epo ti ijoba yo.

Igbese yii lo waye nileese Ijoba Ogun to wa ni Okemosan nilu Abeokuta to je Olu Ipinle Ogun lojo Aje tó kọjá yii.
Gomina ni inu oun dun fun aseyori akanse ise yii ati wipe laipe jojo ni won yoo tun siso loju awon Oko elese meta ( Tricycle ) ati alupupu ti yoo maa lo ina dipo epo bentiroluu. O wa soo di mimo wipe awon ibudo ti awon awako ti yoo maa wa boosi ti o n lo afefe Compressed Natural Gas (CNG) yii yoo ti maa ro afefe pada sinu oko fun lilo won lasiko yii ni Obada Oko nijoba ibile Ewekoro nipinle Ogun ati wipe ibudo fun afefe (CNG) ati Oko boosi naa yoo to wa kaakiri ati jakejado Ipinle Ogun.

Leave a Reply

Back To Top