Agbarijo awon igbimo to n pepe fun isakoso ati ayipada rede lorileede yii ti ro ẹni to ti figba kan ri je Igbakeji aare Lorileede yii, to tun je adije Dupo aare labe egbe oselu Peoples Democratic Party PDP, Alhaji Atiku Abubakar ati akegbe re latinu egbe oselu Labour, Peter Obi lati mase fi orileede yii sile Latari bi ile ejo giga Julo Nile yii lana Ojobo tun se ti fidi re mule pe Aare Bola Ahmed Tinubu naa lo tun jawe olubori ninu idibo sipo aare to waye Koja ninu odun yii gege bi ajo.INEC se kede re.
Awon igbimo yii lo n parowa yii niwaju gbogan Eagle square to wa ninu Abuja.
Igbimo awon adajo eleni meje ti ile ejo giga julo nile yii leyi ti Adajo John Okoro lewaju won ni won ti da ejo ti Peter Obi ati Atiku pe Aare Tinubu leyi ti won fin tako ijawe olubori re ninu idibo ohun eyi ti won gbe wa sile ejo giga julo lote yii.pe iwe eri ti Bola Tinubu yonda fun ajo INEC lati dije eyi to je ti ile eko giga ti Chicago State University lati orileede Amerika wipe iwe eri naa kii se ogidi ile ejo ti wa je ki o di mimo fun Atiku ati Peter Obi wipe ko si eri to fidi re mule wipe Aare Tinubu se alumokoroyi tabi o yi iwe eri naa gege bi esun ti won fi kan-an.
Awon igbimo tó n pepe fun isakoso ati ayipada rere lorileede yii wa parowa fun Atiku ati Obi lati mase fi ibinu kuro lorileede yii latarii abajade ejo naa bikose pe ki won gbaruku ti Aare Tinubu lati tuko orileede yii siwaju .